Anglican Hymnal
Awake, my soul, and with the sun
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 1: Awake, my soul, and with the sun
Ji, okan mi, ba orun ji
Hymn:
1
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Orin Owuro
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
APA I
f
Ji, ọkàn mi, ba orùn ji,
Mura si iṣẹ òjọ rẹ;
Má ṣe ilọra, ji kùtu,
K’ o san gbèse ẹbọ orọ̀
mp
Rò gbogb’ ọjọ t’ o fi ṣòfo;
Bẹrẹ si rere ‘se loni;
Kiyes’ ìrìn rẹ laiye yi;
K’o sì mura d’ọjọ nla nì.
mf
Gbà ninu imolẹ ọrun,
Si tanmọlẹ nà f’ẹlomi;
Jẹ ki ogo Ọlọrun rẹ
Hàn n’nu ìwa at’ise re.
f
Ji, gbọn’ra nù, ‘wọ ọkàn mi,
Yàn ipò rẹ larin Angel,
Awọn ti nwọn nkọrin iyìn
Ni gbogbo oru s’ Ọba wa. Amin.
APA II
Mo ji, mo ji, ogun ọrun,
K’ emi l’agbara bi ti nyin;
K’ emi ba le lo ọjọ mi
Fun iyìn Olugbala mi.
mf
Ogo fun Enit’ o ṣọ mi,
T’o tù mi lara loj’ orun;
Oluwa ijọ mo ba ku,
Ji mi s’aiye ainipẹkun.
p
Oluwa mo tún ẹ̀jẹ́ jẹ,
Tu ẹ̀sẹ ka b’ ìri orọ;
Ṣọ akọronu mi oni,
Si f’Ẹmi Rẹ kun inu mì
cr
Ọrọ at’ iṣe mi oni
Ki nwọn le ri bi ẹkọ Rẹ;
f
K’ emi si f’ ipà mi gbogbo
Ṣiṣẹ rere fun Ogo Rẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites